Menu

Saamu 125

BIB

1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni, tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.

2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

4 Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere, àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.

5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate