Menu

Saamu 126

BIB

1 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.

2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.

3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀.

4 Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù.

5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.

6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate