Menu

Saamu 124

BIB

1 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

2 ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,

3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,

4 nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,

5 nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.

6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.

7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ.

8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate