Menu

Saamu 83

BIB

1 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.

2 Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.

3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.

4 Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè, kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

5 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

6 Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli, ti Moabu àti ti Hagari

7 Gebali, Ammoni àti Amaleki, Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.

8 Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

9 Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,

10 ẹni tí ó ṣègbé ní Endori tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu, àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,

12 tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

14 Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,

15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.

16 Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn

18 jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa: pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate