Menu

Saamu 82

BIB

1 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá, ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?

3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba; ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.

4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní; gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

5 “Wọn kò mọ̀ ohun kankan, wọn kò lóye ohun kankan. Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn; à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

6 “Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”; ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’

7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán; ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate