Menu

Saamu 87

BIB

1 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;

2 Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

3 Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run,

4 “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

5 Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”

6 Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

7 Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate