Menu

Saamu 3

BIB

1 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

7 Dìde, Olúwa! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n; kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá. Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate