Menu

Saamu 129

BIB

1 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá,” jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;

2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá; síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.

3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn.

4 Olódodo ni Olúwa: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”

5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.

6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè,

7 èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀: bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.

8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé, ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate