Menu

Saamu 103

BIB

1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

3 ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,

4 ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,

5 ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ni lára.

7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;

8 Olúwa ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,

10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa.

11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

14 nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó,

16 afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.

17 Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,

18 sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run, ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, tì ó sì ń se ìfẹ́ rẹ̀.

21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ibi gbogbo ìjọba rẹ̀. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate