Menu

Ẹkún Jeremiah 5

BIB

1 Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

2 Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.

3 Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.

4 A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.

5 Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

6 Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.

7 Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8 Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9 Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù.

10 Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.

11 Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.

12 Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn; kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.

13 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

14 Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.

15 Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.

16 Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.

17 Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.

18 Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

19 Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

20 Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

21 Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,

22 àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate