Menu

Jobu 25

BIB

1 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,

2 “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.

3 Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?

4 Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?

5 Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,

6 kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate